Happy Father’s Day
Ṣáákì Ọkùnrin
Ìba ọkùnrin tótó,
Ẹkùn ọkọ òkè mo kí yín,
Akọ igi ti kò gbọdọ̀ ṣe oje,
Akọ òkúta tí ń tẹ orí irin bá.
Ọkùnrin ni bàbá,
Ọkùnrin ni baálé ilé,
Àrẹmọ ilé ti o jẹ kí ilé ó di ahoro,
Aróle ti n róle dẹni bí a o sí nílé.
Ọkùnrin ni aláṣẹ ilé,
Ọkọ ìyàwó ti n kowo ọbẹ sílẹ,
Olútọjú ilé bàbá bukata,
Aforilaku lọjọ́ ògún lè.
Osuba ràbàntà fún igi àràbà,
Igi lẹyìn ọgbà fún tọmọ tìyá,
Ìrókò tó pẹ́ka títí,
Ti ẹ̀kan rẹ n dagba gbẹbọ.
Akọ ni ogidan n bi,
Ẹni bímọ bi akọ kò kú akunrun,
Olú ọmọ tí ń gbé orúkọ bàbá ro,
Apesin ọmọ tí ń gbé oríkì ẹbí ní ìyí.
A kìí pé tí ọkùnrin báwo nínú ẹbí,
Bi ọmọkùnrin o jù konko lọ́ ọkùnrin ni yóò má jẹ,
Ta ni pé ti ọkọ báwo nínú ilé.
Òkè òkun lókú rẹ bàbá ọmọ ló ní ọmọ,
Aya ọlẹ̀ ni a n gbà, a kìí gbà ọmọ ọlẹ̀,
Alubarika ọmọ n bẹ lẹnu bàbá,
Àṣẹ ẹnu bàbá ní n sìn ọmọbìnrin re ilé ọkọ.
Ọkùnrin ni àpáta ayérayé,
Ọkùnrin ni àkọ́kọ́ dà, ọkùnrin ni akeyinde gbẹgbọn, irin nlá ni ọkùnrin ti kìí fi ìgba kan dogun.
Ọkùnrin o ni di arúgbó, ko ma lè ṣe iṣẹ akọ,
Lobolobo ti n bẹ ni isalẹ ko ni yé gbérí,
Olororo ìtura l’ọkunrin kosemani níwòn,
Adájọ atọ idi rẹ k’ayé, a s’obinrin di abiyamọ.
Ọkùnrin kìí ṣe ẹni arinfin, awo
Ọkùnrin ni ọba, àwọn ni mọgaji àti dawodu ìdílé gbogbo.
Ọkùnrin ni ewú yé lọrùn rẹ,
Awo fìlà gígẹ́ ba mú rẹgi,
Aguntaṣọ lo ọkọ arẹwa,
Kúrú kii, sẹ́kẹ̀rẹ̀ owó ti n pé ẹgbẹ bàbá rẹ ràn n’isẹ.
Ibi tó ba le ni a n ba ọmọkùnrin,
Ọkùnrin ọkọ, ọkùnrin oro,
Ọkùnrin ni o le fojú kan oro, àwọn ni ngbé eégún,
Alaya bi ará ni ọkùnrin gan-gan.
ọkùnrin, akọni lójú Ogun, àrònì níbí ìjà,
Bàbá ni bàbá yóò má jẹ ọkùnrin o ni ré ilé,
Ẹkùn ọkọ òkè, lókè lókè ni adé orí ọba ọkùnrin yóò má wà.
A kú ayajọ̀ àwọn Bàbá.
Happy Father’s Day
